Add parallel Print Page Options

12 Efraimu ń jẹ afẹ́fẹ́;
    o ń lépa afẹ́fẹ́ ìwọ̀-oòrùn ní gbogbo ọjọ́.
    O sì ń gbèrú nínú irọ́
o dá májẹ̀mú pẹ̀lú Asiria
    o sì fi òróró olifi ránṣẹ́ sí Ejibiti.
2 Olúwa ní ẹjọ́ kan tí yóò bá Juda rò,
    yóò fì ìyà jẹ Jakọbu gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀
    yóò sì sán fún un gẹ́gẹ́ bí i ìṣe rẹ̀.
3 Láti inú oyún ni ó ti di arákùnrin rẹ̀ mú ni gìgísẹ̀,
    àti nípa ipá rẹ̀ ó ni agbára pẹ̀lú Ọlọ́run
4 Ó bá angẹli ja ìjàkadì, ó sì borí rẹ̀
    o sọkún, ó sì bẹ̀bẹ̀ fún ojúrere rẹ̀
Ó bá Olúwa ní Beteli
    Ó sì bá a sọ̀rọ̀ níbẹ̀,
5 àní Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun;
    Olúwa ni orúkọ ìrántí rẹ̀
6 Ṣùgbọ́n ìwọ gbọdọ̀ padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run rẹ̀;
    di ìfẹ́ àti ìdájọ́ òdodo mú
    kí ẹ sì dúró de Ọlọ́run yín nígbà gbogbo.

7 Oníṣòwò ń lo òṣùwọ̀n èké
    o fẹ́ràn láti rẹ́ ni jẹ.
8 (A)Efraimu gbéraga,
    “Èmi ní ìní fún ara mi, mo sì ti di ọlọ́rọ̀,
pẹ̀lú gbogbo ọrọ̀ mi yìí, wọn kò le ká àìṣedéédéé
    tàbí ẹ̀ṣẹ̀ kankan mọ́ mi lọ́wọ́.”

9 “Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ;
    ẹni tí ó mu ọ jáde wá láti ilẹ̀ Ejibiti;
èmi yóò tún mú yín gbé nínú àgọ́
    bí i ọjọ́ àjọ̀dún tí a yàn wọ̀n-ọn-nì
10 Mo sọ fún àwọn wòlíì,
    mo fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìran hàn wọ́n
    mo sì pa òwe láti ẹnu wòlíì wọn.”

11 Gileadi ha burú bí?
    Àwọn ènìyàn rẹ̀ jẹ́ asán.
Ǹjẹ́ wọ́n ń fi akọ màlúù rú ẹbọ ní Gilgali?
    Gbogbo pẹpẹ wọ́n sì dàbí ebè
    nínú aporo oko.
12 Jakọbu sálọ si orílẹ̀-èdè Aramu;
    Israẹli sìn kí o tó fẹ́ ìyàwó
    ó ṣe ìtọ́jú ẹran láti fi san owó ìyàwó.
13 Olúwa lo wòlíì kan láti mú Israẹli jáde wá láti Ejibiti,
    nípasẹ̀ wòlíì kan ó ṣe ìtọ́jú rẹ̀.
14 Ṣùgbọ́n Efraimu ti mú un bínú gidigidi;
    Olúwa rẹ̀ yóò sì fi ẹ̀bi ìtàjẹ̀ sílẹ̀ sí orí rẹ̀
    òun yóò sì san án padà fún un nítorí ìwà ẹ̀gàn an rẹ̀.