Add parallel Print Page Options

Ìwòsàn ń bẹ fún àwọn tó ronúpìwàdà

14 Yípadà ìwọ Israẹli sí Olúwa Ọlọ́run rẹ.
    Ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ló fa ìparun rẹ!
2 (A)Ẹ gba ọ̀rọ̀ Olúwa gbọ́,
    kí ẹ sì yípadà sí Olúwa.
Ẹ sọ fún un pé:
    “Darí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá
kí o sì fi oore-ọ̀fẹ́ gbà wá,
    kí àwa kí ó lè fi ètè wa sán an fún ọ
3 Asiria kò le gbà wá là;
    A kò ní í gorí ẹṣin ogun
A kò sì ní tún sọ ọ́ mọ́ láé
    ‘Àwọn ni òrìṣà wa
sí àwọn ohun tí ó fi ọwọ́ wa ṣe;
    nítorí pé lọ́dọ̀ rẹ ni àwọn
    aláìní baba tí ń rí àánú.’

4 “Èmi wo àgàbàgebè wọn sàn,
    Èmi ó sì fẹ́ràn wọn, lọ́fẹ̀ẹ́,
    nítorí ìbínú mi ti yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn.
5 Èmi o dàbí ìrì sí Israẹli
    wọn o sì yọ ìtànná bi ewéko lílì
Bi kedari ti Lebanoni yóò si ta gbòǹgbò
6     Àṣẹ̀ṣẹ̀yọ ẹ̀ka rẹ̀ yóò dàgbà,
Dídán ẹwà yóò rẹ̀ dànù bí igi olifi
    Òórùn rẹ yóò sì dàbí igi kedari ti Lebanoni.
7 Àwọn ènìyàn yóò tún padà gbé lábẹ́ òjijì rẹ̀.
    Yóò rúwé bi ọkà.
Yóò sì yọ ìtànná bi àjàrà,
    òórùn rẹ yóò dàbí ti wáìnì Lebanoni.
8 Ìwọ Efraimu; Kín ló tún kù tí mo ní ṣe pẹ̀lú ère òrìṣà?
    Èmi ó dá a lóhùn, èmi ó sì ṣe ìtọ́jú rẹ.
Mo dàbí igi junifa tó ń fi gbogbo ìgbà tutù,
    èso tí ìwọ ń so si ń wá láti ọ̀dọ̀ mi.”

9 (B)Ta ni ọlọ́gbọ́n? Òun yóò mòye àwọn nǹkan wọ̀nyí
    Ta a ní ó mọ̀? Òun yóò ní ìmọ̀ wọn.
Títọ́ ni ọ̀nà Olúwa
    àwọn olódodo si ń rìn nínú wọn
    Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́tẹ̀ ni yóò kọsẹ̀ nínú wọn.