Add parallel Print Page Options

Àsọtẹ́lẹ̀ lòdì sí Moabu

15 (A)Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Moabu:
A pa Ari run ní Moabu,
    òru kan ní a pa á run!
A pa Kiri run ní Moabu,
    òru kan ní a pa á run!
2 Diboni gòkè lọ sí tẹmpili rẹ̀,
    sí àwọn ibi gíga rẹ̀ láti sọkún,
Moabu pohùnréré lórí Nebo àti Medeba.
    Gbogbo orí ni a fá
    gbogbo irùngbọ̀n ni a gé dànù.
3 Wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀ ní ojú òpópónà,
    ní àwọn òrùlé àti àwọn gbàgede ìlú.
Wọ́n pohùnréré
    Wọ́n dọ̀bálẹ̀ pẹ̀lú ẹkún.
4 Heṣboni àti Eleale ké sóde,
    ohùn wọn ni a gbọ́ títí fi dé Jahasi.
Nítorí náà ni àwọn ọmọ-ogun Moabu ṣe kígbe
    tí ọkàn wọn sì rẹ̀wẹ̀sì.

5 Ọkàn mi kígbe sókè lórí Moabu;
    àwọn ìsáǹsá rẹ sálà títí dé Soari,
títí fi dé Eglati-Ṣeliṣi.
    Wọ́n gòkè lọ títí dé Luhiti
wọ́n ń sọkún bí wọ́n ti ń lọ,
    Ní òpópónà tí ó lọ sí Horonaimu
    wọ́n ń pohùnréré ìparun wọn
6 Gbogbo omi Nimrimu ni ó ti gbẹ
    àwọn koríko sì ti gbẹ,
gbogbo ewéko ti tán
    ewé tútù kankan kò sí mọ́.
7 Báyìí gbogbo ọrọ̀ tí wọ́n ti ní
    tí wọ́n sì tò jọ
wọ́n ti kó wọn kọjá lọ lórí i gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́
    odò Poplari.
8 Gbohùngbohùn ń gba igbe wọn dé
    ìpẹ̀kun ilẹ̀ Moabu;
ìpohùnréré wọn lọ títí dé Eglaimu,
    igbe ẹkún wọn ni a gbọ́ títí dé kànga Elimu.
9 Omi Dimoni kún fún ẹ̀jẹ̀,
    síbẹ̀ èmi ó tún mu ohun tí ó jù báyìí lọ wá sórí Dimoni—
kìnnìún kan wá sórí àwọn ìsáǹsá Moabu
    àti lórí àwọn tí ó tún ṣẹ́kù sórí ilẹ̀ náà.