Add parallel Print Page Options

Ayọ̀ àwọn ẹni ìràpadà

35 Aginjù àti ìyàngbẹ ilẹ̀ yóò yọ̀ fún wọn;
    aginjù yóò ṣe àjọyọ̀ yóò sì kún fún ìtànná.
    Gẹ́gẹ́ bí ewéko,
2 Ní títanná yóò tanná;
    yóò yọ ayọ̀ ńláńlá yóò sì kọrin.
Ògo Lebanoni ni a ó fi fún un,
    ẹwà Karmeli àti Ṣaroni;
wọn yóò rí ògo Olúwa,
    àti ẹwà Ọlọ́run wa.

3 (A)Fún ọwọ́ àìlera lókun,
    mú orúnkún tí ń yẹ̀ lókun:
4 Sọ fún àwọn oníbẹ̀rù ọkàn pé
    “Ẹ ṣe gírí, ẹ má bẹ̀rù;
Ọlọ́run yín yóò wá,
    òun yóò wá pẹ̀lú ìgbẹ̀san;
pẹ̀lú ìgbẹ̀san mímọ́
    òun yóò wá láti gbà yín là.”

5 (B)Nígbà náà ni a ó la ojú àwọn afọ́jú
    àti etí àwọn odi kì yóò dákẹ́.
6 Nígbà náà ni àwọn arọ yóò máa fò bí àgbọ̀nrín,
    àti ahọ́n odi yóò ké fún ayọ̀.
Odò yóò tú jáde nínú aginjù
    àti àwọn odò nínú aṣálẹ̀.
7 Ilẹ̀ iyanrìn yíyan yóò di àbàtà,
    ilẹ̀ tí ń pòǹgbẹ yóò di orísun omi.
Ní ibùgbé àwọn dragoni,
    níbi tí olúkúlùkù dùbúlẹ̀,
    ni ó jẹ́ ọgbà fún eèsún àti papirusi.

8 Àti òpópónà kan yóò wà níbẹ̀:
    a ó sì máa pè é ní ọ̀nà Ìwà Mímọ́.
Àwọn aláìmọ́ kì yóò tọ ọ̀nà náà;
    yóò sì wà fún àwọn tí ń rìn ní ọ̀nà náà,
    àwọn ìkà búburú kì yóò gba ibẹ̀ kọjá.
9 Kì yóò sí kìnnìún níbẹ̀,
    tàbí kí ẹranko búburú kí ó dìde lórí i rẹ̀;
a kì yóò rí wọn níbẹ̀.
    Ṣùgbọ́n àwọn ẹni ìràpadà nìkan ni yóò rìn níbẹ̀,
10 àwọn ẹni ìràpadà Olúwa yóò padà wá.
    Wọn yóò wọ Sioni wá pẹ̀lú orin;
ayọ̀ ayérayé ni yóò dé wọn ní orí.
    Ìdùnnú àti ayọ̀ ni yóò borí i wọn,
    ìkorò àti ìtìjú yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ wọn.