Add parallel Print Page Options

Ọdún ojúrere Olúwa

61 (A)Ẹ̀mí Olúwa Olódùmarè wà lára mi
    nítorí Olúwa ti fi ààmì òróró yàn mí
láti wàásù ìhìnrere fún àwọn tálákà.
    Ó ti rán mi láti ṣe àwòtán oníròbìnújẹ́
láti kéde ìdásílẹ̀ fún àwọn ìgbèkùn
    àti ìtúsílẹ̀ kúrò nínú òkùnkùn fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n,
2 Láti kéde ọdún ojúrere Olúwa
    àti ọjọ́ ẹ̀san ti Ọlọ́run wa,
    láti tu àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú,
3 àti láti pèsè fún àwọn tí inú wọn bàjẹ́ ní Sioni
    láti dé wọn ládé ẹwà dípò eérú,
òróró ayọ̀ dípò ọ̀fọ̀,
    àti aṣọ ìyìn dípò ìpòrúru ọkàn.
A ó sì pè wọ́n ní igi óákù òdodo,
    irúgbìn Olúwa
    láti fi ọláńlá rẹ̀ hàn.

4 Wọn yóò tún àwọn ahoro àtijọ́ kọ́
    wọn yóò sì mú àwọn ibi ìparun àtijọ́-tijọ́ náà bọ̀ sípò;
wọn yóò jí àwọn ahoro ìlú náà padà
    tí a ti parun láti ìrandíran sẹ́yìn.
5 Àwọn àjèjì ni yóò máa da ọ̀wọ́ ẹran rẹ;
    àwọn àlejò yóò sì ṣiṣẹ́ nínú oko àti ọgbà àjàrà rẹ.
6 A ó sì máa pè yín ní àlùfáà Olúwa,
    a ó pè yín ní ìránṣẹ́ Ọlọ́run wa.
Ẹ ó máa jẹ nínú ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè
    àti nínú ọrọ̀ wọn ni ẹ̀yin yóò máa ṣògo.

7 Dípò àbùkù wọn
    àwọn ènìyàn mi yóò gba ìlọ́po méjì,
àti dípò àbùkù wọn
    wọn yóò yọ̀ nínú ìní wọn;
bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò sì jogún ìlọ́po méjì ní ilẹ̀ wọn,
    ayọ̀ ayérayé yóò sì jẹ́ tiwọn.

8 “Nítorí Èmi, Olúwa fẹ́ràn ìdájọ́ òdodo;
    mo kórìíra olè jíjà àti ẹ̀ṣẹ̀
Ní òtítọ́ mi èmi yóò sẹ̀san fún wọn
    èmi yóò sì dá májẹ̀mú ayérayé pẹ̀lú wọn.
9 A ó mọ ìrandíran wọn láàrín àwọn orílẹ̀-èdè
    àti àwọn ìran wọn láàrín àwọn ènìyàn
Gbogbo àwọn tí ó bá rí wọn yóò mọ̀ pé
    wọ́n jẹ́ àwọn ènìyàn tí Olúwa ti bùkún.”

10 Èmi yọ̀ gidigidi nínú Olúwa;
    ọkàn mi yọ̀ nínú Ọlọ́run mi.
Nítorí ó ti wọ̀ mí ní aṣọ ìgbàlà
    ó sì ṣe mí lọ́ṣọ̀ọ́ nínú aṣọ òdodo;
gẹ́gẹ́ bí ọkọ ìyàwó ti ṣe orí rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ bí àlùfáà,
    àti bí ìyàwó ṣe ń ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú ohun ọ̀ṣọ́.
11 Gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ti í mú irúgbìn jáde
    àti bí ọgbà ṣe ń mú irúgbìn dàgbà,
Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa Olódùmarè yóò ṣe mú òdodo àti ìyìn
    kí ó ru sókè níwájú gbogbo orílẹ̀-èdè.