Add parallel Print Page Options

Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.

64 Gbóhùn mi, Ọlọ́run, bí mo ti ń sọ àròyé mi
    pa ọkàn mi mọ́ kúrò lọ́wọ́ ẹ̀rù àwọn ọ̀tá.

2 Pa mí mọ́ kúrò lọ́wọ́ ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ àwọn ènìyàn búburú
    kúrò nínú ọ̀pọ̀ igbe lọ́wọ́ ìrúkèrúdò oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.
3 Wọ́n pọ́n ahọ́n wọn bí idà,
    wọ́n sì fa ọrun wọn le láti tafà wọn, àní ọ̀rọ̀ kíkorò.
4 Wọ́n tafà ní ìkọ̀kọ̀ sí àwọn aláìlẹ́ṣẹ̀:
    wọ́n tafà si lójijì, wọn kò sì bẹ̀rù.

5 Wọ́n, gba ara wọn níyànjú nínú èrò búburú,
    wọ́n sọ̀rọ̀ lórí dídẹkùn sílẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀
    wọ́n wí pé, “Ta ni yóò rí wa?”
6 Wọ́n gbìmọ̀ àìṣòdodo, wọ́n wí pé,
    “A wa ti parí èrò tí a gbà tán”
    lóòótọ́ àyà àti ọkàn ènìyàn kún fún àrékérekè.

7 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò ta wọ́n ní ọfà;
    wọn ó sì gbọgbẹ́ lójijì.
8 Ahọ́n wọn yóò sì dojú ìjà kọ wọ́n, yóò sì run wọ́n,
    Gbogbo ẹni tí ó bá rí wọn yóò sì mi orí fún wọn.
9 Gbogbo ènìyàn yóò máa bẹ̀rù
    wọn ó kéde iṣẹ́ Ọlọ́run
    wọn ó dúró lé ohun tí ó ṣe.

10 Jẹ́ kí olódodo kí ó yọ̀ nínú Olúwa
    yóò sì rí ààbò nínú rẹ̀.
    Gbogbo ẹni ìdúró ṣinṣin ní ọkàn yóò máa yìn ín.