Add parallel Print Page Options

Orin. Saamu ti Asafu.

83 Ọlọ́run, má ṣe dákẹ́;
    Má ṣe dákẹ́, Ọlọ́run má ṣe dúró jẹ́ẹ́.
2 Wo bí àwọn ọ̀tá rẹ ti ń rọ́kẹ̀kẹ̀ lọ,
    bi àwọn ọ̀tá rẹ ti ń gbé ohùn wọn sókè.
3 Pẹ̀lú àrékérekè ni wọn dìtẹ̀ sí àwọn ènìyàn rẹ;
    wọn sí dìtẹ̀ mọ́ àwọn tí o fẹ́.
4 Wọn wí pé, “wá, ẹ jẹ́ kí á pa wọ́n run bí orílẹ̀-èdè,
    kí orúkọ Israẹli ma bá a sí ní ìrántí mọ́.”

5 Wọ́n gbìmọ̀ pọ̀ pẹ̀lú ọkàn kan;
    wọ́n ṣe àdéhùn láti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ
6 Àgọ́ Edomu àti ti àwọn ará Iṣmaeli,
    ti Moabu àti ti Hagari
7 Gebali, Ammoni àti Amaleki,
    Filistia, pẹ̀lú àwọn ènìyàn Tire.
8 Asiria pẹ̀lú ti darapọ̀ mọ́ wọn
    láti ran àwọn ọmọ Lọti lọ́wọ́. Sela.

9 Ṣe sí wọn bí ìwọ ti ṣe sí Midiani
    bí o ti ṣe sí Sisera àti Jabini ní odò Kiṣoni,
10 Ẹni tí ó ṣègbé ní Endori
    tí wọn sì dàbí ààtàn ní orí ilẹ̀.
11 Ṣe àwọn ọlọ́lá wọn bí Orebu àti Seebu,
    àwọn ọmọ-aládé wọn bí Seba àti Salmunna,
12 Tí ó wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a gbà ní ìní
    àní pápá oko tútù Ọlọ́run.”

13 Ìwọ Ọlọ́run, ṣe wọ́n bí ààjà,
    bí ìyàngbò níwájú afẹ́fẹ́.
14 Bí iná ti í jó igbó,
    àti bí ọ̀wọ́-iná ti ń mú òkè ńlá gbiná,
15 Bẹ́ẹ̀ ni kí o fi ẹ̀fúùfù líle rẹ lépa wọn
    dẹ́rùbà wọn lójú pẹ̀lú ìjì rẹ.
16 Fi ìtìjú kún ojú wọn,
    kí àwọn ènìyàn bá à lè ṣe àfẹ́rí orúkọ rẹ àti kí o fi ìjì líle rẹ dẹ́rùbà, ìwọ Olúwa.

17 Jẹ́ kí ojú kí ó tì wọ́n, kí wọ́n sì dààmú láéláé
    kí wọ́n ṣègbé sínú ẹ̀gàn
18 Jẹ́ kí wọn mọ̀ pé ìwọ, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúwa:
    pé ìwọ nìkan ní Ọ̀gá-ògo jùlọ lórí gbogbo ayé.